Kabiyesi O
Alade wura
Eru jejeje, ti n migbo kiji kiji
Kabiyesi O
Oluwa mi
Adeda Aseda
Oba ti n je Emini Emini
Oba ti n je Emini mase beru
Alpha omega
Aterere kaari aye
Arugbo Ojo
Oba to n taye beni n teni
To foju orun bora bi aso
To fimole bole bi aso
Kabiyesi ni
Baba mi ni
Agbani lagbato
Ogbagba ti n gbalaini
Olowo gbogbo ro ti n yomo re nu ofo
Ibere ati Opin owun gbogbo
Oba awon oba
Oluwa awon oluwa
Baba mi ni
Mo wa dupe ola ore Re
Mo wa dupe ola ore Re o
Loori mi
Emi o ni gbagbe Re o mama se o Baba
Baba ose ose
ore Re loori mi
Emi o ni gbagbe Re o
mama se o Baba
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment